Ìwé Àkàgbó̩ L’órí Àwo̩n Isé̩ Alàgbà D. O. Fágúnwà

//Ìwé Àkàgbó̩ L’órí Àwo̩n Isé̩ Alàgbà D. O. Fágúnwà
­

Ìwé Àkàgbó̩ L’órí Àwo̩n Isé̩ Alàgbà D. O. Fágúnwà

Omo Kaaro Oojiire, e nle nbeun o, ara o le bi?

Idunnu nla ni fun mi lati gbe igbese l’ori si se “Iwe Akagbo” l’ori awon iwe Alagba D. O. Fagunwa, eniti o di oloogbe nigbati ojo ori re di ogofa, ati l’ori awon iwe Alagba Akinwumi Ishola ati beebee lo.

E jowo e gaafara fun mi ki nso oro ranpe l’ori awon iwe Alagba Fagunwa. Alagba Fagunwa je eniti o ni imo pupo ti Olorun si tun fi ooye ati ogbon ijinle fun. Gegebi iwadi ti a se, Alagba Fagunwa je eni akoko ni ile Yoruba ti yio koko ko iru iwe itan aroso ti o ko ni igba aye re. Awon iwe ti Alagba Fagunwa ko ni, Igbo Olodumare, Ireke Onibudo, Ogboju Ode Ninu Igbo Irunmole, Irinkerindo Ninu Igbo elegbeje ati Adiitu Olodumare. Bi oti je wi pe, gbogbo awon iwe yi ni won je itan nipa iriri aye awa eda, isesii wa, ati irin ajo wa ninu aiye yi, bakan na awon iwe naa ko wa ni ogbon pupo nipa gbigbe ninu aye yi. Ninu gbogbo awon iwe marun ti Alagba Fagunwa ko, Ogboju Ode Ninu Igbo Irunmole je iwe ti a le pe ni “opomulero” (ti eyin oloyinbo npe ni flagship) gbogbo awon iwe itan aroso yoku. Iwe Alagba Fagunwa je iwe ti ogunlogo awon eniyan l’ode oni ti nse iwadi nipa won, ati paapaa julo lori eyi ti akole re nje, Ogboju Ode Ninu Igbo Irunmole.

Iru igbese ti a gbe l’ori awon iwe wonyi eyi tii se “Iwe kika Akagbo” je iru ise akoko se (Pioneer), nitori wi pe akagbo yi ni awon eto iriri ti nse apejuwe fun gbogbo ohun ti nse’le ninu itan naa. Fun apeere, a fi ohun eye ati eranko si apa ibi ti Akaara Oogun wa ninu igbo; apejuwe ekun, ija jija, erin rinrin ati beebee lon fun apejuwe awon apa inu iwe na ti o je moa won apejuwe ti a so yi. Iru ise yi ni ao ba pe ni odikeji sinimo (cinema) tabi muvi (movie), sugbon ti o je wi pe kaka ki a ma wo itan yi ni aworan, gbígbo ni a ngbo.

Iru ise bayi ko wo po, eyi naa ni o je ki inu Olori ile ise ti won ti se iwe na, (Evans/Nelson Publisher) dun ti o si fi owo si ifowosowopo pelu ile ise wa nipa sise “Iwe kika Akagbo” naa. Ohun to se ni laanu ni wi pe, Olori ile ise yi ti ati jo nsoro l’ori ibasepo pelu wa lori ise nla yi, di oloogbe ni osu kesan odun ti a wa yi. Ki Olorun ba wa te won si afefe rere.

Gegebi e ti se mo, wipe bi eniyan ba ku, eniyan niiku, toto o se bi owe o. Lehin ipapoda Ogbeni Oloriile ise Evans ti atehin wa, eniti o ti wa bo si ipo lati de’le ki won to yan asoju miran fi wa lokan bale wi pe ise wa yio te siwaju dajudaju, nitori wi pe ise nla yi ise daadaa ni, eyi ti yio tun bu iyi nla fun ile ise awon. Paapaa julo, o tun fi ye wa wi pe oun mo nipa gbogno akitiyan ti a ti nse l’ori oro ifowosowopo laarin Evans/Nelson ati M-SYSTEMS Canada Corp, ti won si fi wa l’okan ba’le wi pe awon yio tete se ohun gbogbo yoku ti a ni lati se fun itesiwaju ise yi. A dupe lowo won.

Toooo eyin omo kaaro oojiire, o d’owo yin lati gbe ede wa l’aruge. Itiju nla ni o je wi pe, sasa ni omo Yoruba ti o le so Yoruba ti o da gaara lai se wipe won se amulumola re pelu ede oyinbo. Fun ileri okan ti emi, gbogbo ohun ti o ba wa ni ipaa mi ni emi yio sa lati fi gbe ede, ise, asa, ati isedale Yoruba l’aruge.

E je ki ntoro aforiji fun ojo iwaju, papaa julo ti e ba ka nkankan ni webusaiti wa yi ni oyinbo, ki ise wi pe afi se iyaju si yin, sugbon yio je wi pe ohun akole iwe naa dun ni toobe ti a l’ero wipe o ye ki afi to yin l’eti ni. Ohun miran pataki ti e o tun ni lati kiyesi ni wipe, awon oro oyinbo miran ti a ko ba mo itunmo re ni Yoruba, a o fi ogbon inu gbee lati le yii pada si adalu Yoruba mo Oyinbo, Fun apeere, a o pe website ni webusaiti. A le ro wi pe e o ma ba wa ka lo bi e ba ri won nkan won yi, lalaise wipe e o ma binu siwa, tabi ki e ma kiritisaisi (criticise, (ah! omiran tun leyi o, LOL!)) wa, eyi ti yio wa jo oro, eniti nyo iti igi oju elomiran tio gbagbe nipa iroko ti nbe loju tie, beeni! Mo wa fe bi wa ni ibeere kan, se e o se afunwara ni, tabi e o se ise adete, ti ko le fun wara sugbon ti o le daanu? Owe agba ni o.

Mo ro yin ki e te le mi ka lo ninu irin ajo wa yi lati gbe awon olukoiwe itan aroso Yoruba dede l’aruge.

Lehin ti a ba pari iwe maraarun ti Alagba D. O. Fagunwa, a o bere ise l’ori ti Alagba Akinwumi Isola eniti o ko iwe “O Leku” ati beebee lo.

Gbogbo awon iwe ti a nse ise le l’ori wonyi ni o kun fun opolopo ogbo, ti awon itan won na si dun bi oyin. E seun, e si ku oju l’ona.

Ire O! Ire Kabitikabiti!

Emi ni ti yin ni tooto,

Ogbeni Rotimi Osuntola.

By |June 2nd, 2016|Comments Off on Ìwé Àkàgbó̩ L’órí Àwo̩n Isé̩ Alàgbà D. O. Fágúnwà

Comments are closed.