Omo Kaaro Oojiire, e nle nbeun o, ara o le bi? Nje e ranti Oro Akak’ogbon yi?

ISÉ NI ÒÒGÙN ÌSÉ……..Work is the antidote for poverty

MÚRA SÍ ISÉ RE ÒRÉÈ MI…….Work hard, my friend
ISÉ NI A FI Í DI ENI GIGA…….work is used to elevate one in respect and importance (Aspiring to higher height is fully dependent on hard work)
BÍ A KÒ BÁ RÉNI FÈYÌN TÌ, BÍ ÒLE LÀ Á RÍ;……if we do not have anyone to lean on, we appear indolent
BÍ A KO RÉNI GBÉKÈLÉ,…..if we do not have anyone to trust (we can depend on…)
À A TERA MÓ ISÉ ENI…..we simply work harder
ÌYÁ RE LÈ LÓWÓ LÓWÓ…..your mother may be wealthy
BÀBÁ SÌ LÈ LÉSIN LÉÈKÀN…..your father may have a ranch full of horses
BÍ O BÁ GBÓJÚ LÉ WON,…….. if you depend on their riches alone
O TÉ TÁN NI MO SO FÚN O,……you may end up in disgrace, I tell you
OHUN TÍ A KÒ BA JÌYÀ FÚN,…..whatever gain one does not work hard to earn.
KÌ Í LÈ TÓJÓ…..usually does not last
OHUN TÍ A BÁ FARA SISÉ FÚN,….whatever gain one works hard to earn
NÍ Í PÉ LÓWÓ ENI…..is the one that lasts in one’s hands.(while in ones possession)
APÁ LARÁ, ÌGÙNPÁ NÌYEKAN…… the arm is a relative, the elbow is a sibling
BÍ AYÉ N FÉ O LÓNÌÍ,….you may be loved by all today
BÍ O BÁ LÓWÓ LÓWÓ,……it is when you have money
NI WON Á MÁA FÉ O LÓLA……that they will love you tomorrow
TÀBÍ TÍ O BÁ WÀ NÍ IPÒ ÀTÀTÀ,…..or when you are in a high position
AYÉ Á YÉ O SÍ TÈRÍN-TÈRÍN,…..all will honor you with cheers and smiles
JÉ KÍ O DI ENI N RÁÁGÓ,….wait till you become poor or are struggling to get by
KÍ O RÍ BÁYÉ TI Í SÍMÚ SÍ O……and you will see how all grimace at you as they pass you by
ÈKÓ SÌ TÚN N SONI Í DÒGÁ,…..education also elevates one in position
MÚRA KÍ O KÓ O DÁRADÁRA…..work hard to acquire good education
BÍ O SÌ RÍ ÒPÒ ÈNÌYÀN,…..and if you see a lot of people
TÍ WÓN N FI ÈKÓ SE ÈRÍN RÍN,….making education a laughing stock
DÁKUN MÁ SE FARA WÉ WON…..please do not emulate or keep their company
ÌYÀ N BÒ FÓMO TÍ KÒ GBÓN,…..suffering is lying in wait for an unserious kid
EKÚN N BE FÓMO TÓ N SÁ KIRI…….sorrow is in the reserve for a truant kid
MÁ FÒWÚRÒ SERÉ, ÒRÉÈ MI,…..do not play with your early years, my friend
MÚRA SÍSÉ, OJÓ N LO…..work harder, time and tide wait for no one.